14 àwọn tí wọn ń yọ̀ ninu ìwà ibití wọ́n sì ní inú dídùn sí ìyapa ibi;
15 àwọn tí ọ̀nà wọn wọ́,tí wọ́n kún fún ìwà àrékérekè.
16 A óo gbà ọ́ lọ́wọ́ obinrin oníṣekúṣe,àní lọ́wọ́ obinrin onírìnkurìn pẹlu ọ̀rọ̀ ẹ̀tàn rẹ̀.
17 Ẹni tí ó kọ ọkọ àárọ̀ rẹ̀ sílẹ̀,tí ó sì gbàgbé majẹmu Ọlọrun rẹ̀.
18 Ẹni tí ilé rẹ̀ rì sinu ìparun,tí ọ̀nà rẹ̀ sì wà ninu ọ̀fìn isà òkú.
19 Kò sí ẹni tí ó tọ̀ ọ́ lọ, tí ó pada rí,bẹ́ẹ̀ ni wọn kì í tún pada sí ọ̀nà ìyè.
20 Nítorí náà, máa rìn ní ọ̀nà àwọn eniyan rere,sì máa bá àwọn olódodo rìn.