1 Ẹlẹ́yà ni ọtí waini,aláriwo ní ọtí líle,ẹnikẹ́ni tí a bá fi tànjẹ kò gbọ́n.
2 Ibinu ọba dàbí bíbú kinniun,ẹni tí ó bá mú ọba bínú fi ẹ̀mí rẹ̀ wéwu.
3 Nǹkan iyì ni pé kí eniyan máa yẹra fún ìjà,ṣugbọn òmùgọ̀ eniyan níí máa ń jà.
4 Ọ̀lẹ kì í dáko ní àkókò,nítorí náà, nígbà ìkórè, kò ní rí nǹkankan kó jọ.
5 Èrò ọkàn eniyan dàbí omi jíjìn,ẹni tí ó bá ní ìmọ̀ ló lè fà á jáde.