6 Ọ̀pọ̀ eniyan a máa ka ara wọn kún olóòótọ́,ṣugbọn níbo la ti lè rí ẹyọ ẹnìkan tó jẹ́ olódodo?
7 Olódodo a máa rìn ní ọ̀nà òtítọ́,ibukun ni fún àwọn ọmọ rẹ̀ tí wọ́n tẹ̀lé e.
8 Nígbà tí ọba bá jókòó sórí ìtẹ́ ìdájọ́ rẹ̀,ojú ni yóo fi gbọn àwọn ẹni ibi dànù.
9 Ta ló lè sọ pé ọkàn òun mọ́,ati pé òun mọ́, òun kò ní ẹ̀ṣẹ̀?
10 Ayédèrú òṣùnwọ̀n jẹ́ ohun ìríra lójú OLUWA.
11 Ọmọde pàápàá a máa fi irú eniyan tí òun jẹ́ hàn nípa ìṣe rẹ̀,bí ohun tí ó ṣe dára, tí ó sì tọ̀nà.
12 Ati etí tí ń gbọ́ràn, ati ojú tí ń ríran,OLUWA ló dá ekinni-keji wọn.