1 Orúkọ rere dára láti yàn ju ọrọ̀ pupọ lọ,kí á rí ojurere sì dára ju kí á ní fadaka ati wúrà lọ.
2 Ọlọ́rọ̀ ati talaka pàdé,OLUWA ló dá ekinni-keji wọn.
3 Ọlọ́gbọ́n rí ibi, ó farapamọ́,ṣugbọn òpè ń bá tirẹ̀ lọ láìbìkítà,ó sì kó sinu ìyọnu.
4 Èrè ìrẹ̀lẹ̀ ati ìbẹ̀rù OLUWA ni ọrọ̀, ọlá, ati ìyè.