16 Ẹni tí ó ni talaka lára kí ó lè ní ohun ìní pupọ,tabi tí ó ń ta ọlọ́rọ̀ lọ́rẹ yóo pada di talaka.
17 Tẹ́tí rẹ sílẹ̀ kí o gbọ́ ọ̀rọ̀ ọlọ́gbọ́n,kí o sì fi ọkàn sí ẹ̀kọ́ mi,
18 nítorí yóo dára tí o bá pa wọ́n mọ́ lọ́kàn rẹ,tí o sì ń fi wọ́n ṣe ọ̀rọ̀ sọ jáde.
19 Ìwọ ni mo sọ wọ́n di mímọ̀ fún lónìí, àní ìwọ,kí ó le jẹ́ pé OLUWA ni o gbẹ́kẹ̀lé.
20 Ṣebí mo ti kọ ọgbọ̀n àkọsílẹ̀ fún ọ lórí ìmọ̀ràn ati ọgbọ́n,
21 láti fi ohun tí ó tọ̀nà tí ó sì jẹ́ òtítọ́ hàn ọ́,kí o lè fi ìdáhùn pípé fún ẹni tí ó rán ọ.
22 Má ja talaka lólè, nítorí pé ó jẹ́ talaka,má sì dájọ́ èké fún ẹni tí ara ń ni.