2 Ọlọ́rọ̀ ati talaka pàdé,OLUWA ló dá ekinni-keji wọn.
3 Ọlọ́gbọ́n rí ibi, ó farapamọ́,ṣugbọn òpè ń bá tirẹ̀ lọ láìbìkítà,ó sì kó sinu ìyọnu.
4 Èrè ìrẹ̀lẹ̀ ati ìbẹ̀rù OLUWA ni ọrọ̀, ọlá, ati ìyè.
5 Ẹ̀gún ati tàkúté ń bẹ lọ́nà àwọn ẹlẹ́tàn,ẹni tí ó pa ọkàn rẹ̀ mọ́ yóo jìnnà sí wọn.
6 Tọ́ ọmọ rẹ sí ọ̀nà tí ó yẹ kí ó máa rìn,bí ó bá dàgbà tán, kò ní kúrò ninu rẹ̀.
7 Ọlọ́rọ̀ máa ń jọba lé talaka lórí,ẹni tí ó lọ yá owó sì ni ẹrú ẹni tí ó yá a lówó.
8 Ẹni tí ó bá gbin aiṣododo yóo kórè ìdààmú,pàṣán ibinu rẹ̀ yóo sì parun.