22 Má ja talaka lólè, nítorí pé ó jẹ́ talaka,má sì dájọ́ èké fún ẹni tí ara ń ni.
23 Nítorí OLUWA yóo gbèjà wọn,yóo fìyà jẹ àwọn tí wọn ń jẹ wọ́n níyà.
24 Má bá oníbìínú eniyan kẹ́gbẹ́,má sì bá onínúfùfù da nǹkan pọ̀.
25 Kí o má baà kọ́ ìwà rẹ̀,kí o sì fi tàkúté mú ara rẹ.
26 Má bá wọn ṣe onígbọ̀wọ́ ẹni tó fẹ́ yá owó,má bá wọn ṣe onídùúró fún onígbèsè.
27 Tí o kò bá rí owó san fún olówó,olówó lè pé kí wọn gba ibùsùn rẹ.
28 Má hú ohun tí àwọn baba ńlá rẹ rì mọ́lẹ̀,tí wọ́n fi pa ààlà kúrò.