7 Ọlọ́rọ̀ máa ń jọba lé talaka lórí,ẹni tí ó lọ yá owó sì ni ẹrú ẹni tí ó yá a lówó.
8 Ẹni tí ó bá gbin aiṣododo yóo kórè ìdààmú,pàṣán ibinu rẹ̀ yóo sì parun.
9 Olójú àánú yóo rí ibukun gbà,nítorí pé ó ń fún talaka ninu oúnjẹ rẹ̀.
10 Lé pẹ̀gànpẹ̀gàn síta, ìjà yóo rọlẹ̀,asọ̀ ati èébú yóo sì dópin.
11 Ẹni tí ó fẹ́ ọkàn mímọ́,tí ó sì ní ọ̀rọ̀ rere lẹ́nu yóo bá ọba ṣọ̀rẹ́.
12 Ojú OLUWA ń ṣọ́ ìmọ̀ tòótọ́,ṣugbọn a máa yí ọ̀rọ̀ àwọn alaigbagbọ po.
13 Ọ̀lẹ a máa sọ pé, “Kinniun wà níta!Yóo pa mí jẹ lójú pópó!”