1 Nígbà tí o bá jókòó láti bá ìjòyè jẹun,kíyèsí ẹni tí ó bá wà níwájú rẹ dáradára.
2 Tí o bá jẹ́ wọ̀bìà eniyan, ṣọ́ra,kí o má fi ọ̀bẹ lé ara rẹ lọ́fun.
3 Má jẹ́ kí oúnjẹ aládìídùn rẹ̀ wọ̀ ọ́ lójú,nítorí ó lè jẹ́ oúnjẹ ẹ̀tàn.
4 Má ṣe làálàá àṣejù láti kó ọrọ̀ jọ,fi ọgbọ́n sẹ́ ara rẹ.
5 Kí o tó ṣẹ́jú pẹ́, owó rẹ lè ti lọ,ó le gúnyẹ̀ẹ́ kí ó fò,bí ìgbà tí ẹyẹ àṣá bá fò lọ.