16 N óo láyọ̀ ninu ọkàn minígbà tí o bá ń sọ òtítọ́.
17 Má ṣe ìlara àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀,ṣugbọn máa bẹ̀rù OLUWA lọ́jọ́ gbogbo.
18 Dájúdájú, ọjọ́ ọ̀la rẹ yóo dára,ìrètí rẹ náà kò sì ní já sí òfo.
19 Fetí sí mi, ọmọ mi, kí o sì gbọ́n,darí ọkàn rẹ sí ọ̀nà títọ́.
20 Má bá àwọn ọ̀mùtí kẹ́gbẹ́;tabi àwọn wọ̀bìà, tí wọn ń jẹ ẹran ní àjẹkì;
21 nítorí pé àwọn ọ̀mùtí ati àwọn wọ̀bìà yóo di talaka,oorun àsùnjù a sì máa sọ eniyan di alákìísà.
22 Gbọ́ ti baba tí ó bí ọ,má sì ṣe pẹ̀gàn ìyá rẹ nígbà tí àgbà bá dé sí i.