21 nítorí pé àwọn ọ̀mùtí ati àwọn wọ̀bìà yóo di talaka,oorun àsùnjù a sì máa sọ eniyan di alákìísà.
22 Gbọ́ ti baba tí ó bí ọ,má sì ṣe pẹ̀gàn ìyá rẹ nígbà tí àgbà bá dé sí i.
23 Ra òtítọ́, má sì tà á,ra ọgbọ́n, ẹ̀kọ́ ati òye pẹlu.
24 Baba olódodo ọmọ yóo láyọ̀ pupọ,inú ẹni tí ó bí ọlọ́gbọ́n ọmọ yóo dùn.
25 Mú inú baba ati ìyá rẹ dùn,jẹ́ kí ìyá tí ó bí ọ láyọ̀ lórí rẹ.
26 Ọmọ mi, gbọ́ tèmi,kí o sì máa kíyèsí ọ̀nà mi.
27 Nítorí aṣẹ́wó dàbí ọ̀fìn jíjìn,obinrin onírìnkurìn sì dàbí kànga tí ó jìn.