30 Àwọn tí wọn máa ń pẹ́ ní ìdí ọtí ni,àwọn tí wọn ń mu ọtí àdàlú.
31 Má jẹ́ kí pípọ́n tí ọtí pọ́n fà ọ́ mọ́ra,nígbà tí ó bá ń ta wínníwínní ninu ife,tí o dà á mu, tí ó lọ geere lọ́nà ọ̀fun.
32 Nígbà tí ó bá yá, á máa buni ṣán bí ejò,oró rẹ̀ á sì dàbí ti ejò paramọ́lẹ̀.
33 Ojú rẹ yóo rí nǹkan àjèjì,ọkàn rẹ á máa ro èròkerò.
34 O óo dàbí ẹni tí ó dùbúlẹ̀ lórí agbami òkun,bí ẹni tí ó sùn lórí òpó ọkọ̀.