4 Má ṣe làálàá àṣejù láti kó ọrọ̀ jọ,fi ọgbọ́n sẹ́ ara rẹ.
5 Kí o tó ṣẹ́jú pẹ́, owó rẹ lè ti lọ,ó le gúnyẹ̀ẹ́ kí ó fò,bí ìgbà tí ẹyẹ àṣá bá fò lọ.
6 Má ṣe jẹ oúnjẹ ahun,má ní ìfẹ́ sí oúnjẹ aládìídùn rẹ̀;
7 nítorí ẹni tí ó máa fi ọkàn ṣírò owó oúnjẹ ni.Ó lè máa wí fún ọ pé, “Jẹ, kí o sì mu!”ṣugbọn kò dé inú rẹ̀.
8 O óo pọ gbogbo òkèlè tí o jẹ,gbogbo ọ̀rọ̀ dídùn tí o sọ yóo sì jẹ́ àsọdànù.
9 Má sọ̀rọ̀ létí òmùgọ̀,nítorí yóo gan ọgbọ́n tí ó wà ninu ọ̀rọ̀ tí o sọ.
10 Má ṣe hú ohun tí wọ́n rì mọ́lẹ̀ fi pa ààlà láti ìgbà àtijọ́,má sì gba ilẹ̀ ọmọ aláìníbaba;