9 Má sọ̀rọ̀ létí òmùgọ̀,nítorí yóo gan ọgbọ́n tí ó wà ninu ọ̀rọ̀ tí o sọ.
10 Má ṣe hú ohun tí wọ́n rì mọ́lẹ̀ fi pa ààlà láti ìgbà àtijọ́,má sì gba ilẹ̀ ọmọ aláìníbaba;
11 nítorí pé Olùràpadà wọn lágbára,yóo gba ìjà wọn jà.
12 Fi ọkàn rẹ sí ẹ̀kọ́, kí o sì tẹ́tí sí ọ̀rọ̀ ìmọ̀.
13 Bá ọmọde wí;bí o bá fi pàṣán nà án, kò ní kú.
14 Bí o bá fi pàṣán nà án,o óo gba ẹ̀mí rẹ̀ lọ́wọ́ ikú.
15 Ọmọ mi, bí o bá gbọ́n,inú mi yóo dùn.