21 Ọmọ mi, bẹ̀rù OLUWA ati ọba,má ṣe àìgbọràn sí ọ̀kankan ninu wọn;
22 nítorí jamba lè ti ọ̀dọ̀ wọn wá lójijì,ta ló mọ irú ìparun, tí ó lè ti ọ̀dọ̀ àwọn mejeeji wá?
23 Àwọn ọ̀rọ̀ ọlọ́gbọ́n tún nìwọ̀nyí:Kò dára láti máa ṣe ojuṣaaju ninu ìdájọ́.
24 Ẹni tí ó sọ fún ẹlẹ́ṣẹ̀ pé ọwọ́ rẹ̀ mọ́,àwọn eniyan yóo gbé e ṣépè,àwọn orílẹ̀-èdè yóo sì kórìíra rẹ̀.
25 Ṣugbọn yóo dára fún àwọn tí wọ́n bá dá ẹ̀bi fún ẹni tí ó jẹ̀bi,ibukun Ọlọrun yóo sì bá wọn.
26 Ẹni tí ó bá fèsì tí ó tọ́dàbí ẹni tí ó fi ẹnu koni lẹ́nu.
27 Parí iṣẹ́ tí ò ń ṣe níta,tọ́jú gbogbo nǹkan oko rẹ,lẹ́yìn náà kọ́ ilé rẹ.