25 Ṣugbọn yóo dára fún àwọn tí wọ́n bá dá ẹ̀bi fún ẹni tí ó jẹ̀bi,ibukun Ọlọrun yóo sì bá wọn.
26 Ẹni tí ó bá fèsì tí ó tọ́dàbí ẹni tí ó fi ẹnu koni lẹ́nu.
27 Parí iṣẹ́ tí ò ń ṣe níta,tọ́jú gbogbo nǹkan oko rẹ,lẹ́yìn náà kọ́ ilé rẹ.
28 Má jẹ́rìí lòdì sí aládùúgbò rẹ láìnídìí,má sì jẹ́ kí ọ̀rọ̀ ẹ̀tàn ti ẹnu rẹ jáde.
29 Má sọ pé, “Bí lágbájá ti ṣe sí mi,bẹ́ẹ̀ ni èmi náà yóo ṣe sí i,n óo san ẹ̀san ohun tí ó ṣe fún un.”
30 Mo gba ẹ̀gbẹ́ oko ọ̀lẹ kan kọjá,mo kọjá lẹ́gbẹ̀ẹ́ ọgbà àjàrà ẹnìkan tí kò lóye.
31 Wò ó! Ẹ̀gún ti hù níbi gbogbo,igbó ti bo gbogbo rẹ̀ mọ́lẹ̀,ọgbà tí ó fi òkúta ṣe yí i ká sì ti wó.