9 Ẹ̀ṣẹ̀ ni ète òmùgọ̀,ẹni ìríra sì ni pẹ̀gànpẹ̀gàn.
10 Bí o bá kùnà lọ́jọ́ ìpọ́njú,a jẹ́ pé agbára rẹ kò tó.
11 Gba àwọn tí wọ́n bá fẹ́ lọ pa sílẹ̀,fa àwọn tí wọ́n bá fẹ́ ta gbọ̀n-ọ́n-gbọ̀n-ọ́n,lọ sọ́dọ̀ àwọn apànìyàn pada.
12 Bí ẹ bá sọ pé ẹ kò mọ nǹkan nípa rẹ̀,ṣé ẹni tí ó mọ èrò ọkàn kò rí i?Ṣé ẹni tí ń pa ẹ̀mí rẹ mọ́ kò mọ̀,àbí kò ní san án fún eniyangẹ́gẹ́ bí iṣẹ́ ọwọ́ rẹ̀?
13 Ọmọ mi, jẹ oyin, nítorí pé ó dùn,oyin tí a fún láti inú afárá a sì máa dùn lẹ́nu.
14 Mọ̀ dájú pé bẹ́ẹ̀ ni ọgbọ́n yóo rí fún ọ,bí o bá ní i, yóo dára fún ọ lẹ́yìn ọ̀la,ìrètí rẹ kò sì ní di asán.
15 Má lúgọ bí eniyan burúkú láti kó ilé olódodo,má fọ́ ilé rẹ̀.