1 Àwọn òwe mìíràn tí Solomoni pa,tí àwọn òṣìṣẹ́ Hesekaya ọba Juda kọ sílẹ̀ nìwọ̀nyí.
2 Ògo ni ó jẹ́ fún Ọlọrun láti fi nǹkan pamọ́,ṣugbọn ògo ló sá tún jẹ́ fún ọbaláti wádìí nǹkan ní àwárí.
3 Bí ọ̀run ti ga, tí ilẹ̀ sì jìn,bẹ́ẹ̀ ni ẹnikẹ́ni kò lè mọ ohun tí ó wà lọ́kàn àwọn ọba.
4 Yọ́ gbogbo ìdọ̀tí tí ó wà lára fadaka kúrò,alágbẹ̀dẹ yóo sì rí fadaka fi ṣe ohun èlò.
5 Mú àwọn olùdámọ̀ràn ibi kúrò lọ́dọ̀ ọba,a óo sì fi ìdí ìjọba rẹ̀ múlẹ̀ pẹlu òdodo.