15 Ọ̀lẹ ti ọwọ́ bọ àwo oúnjẹ,ṣugbọn ó lẹ kọjá kí ó lè bu oúnjẹ kí ó fi bọ ẹnu.
16 Ọ̀lẹ gbọ́n lójú ara rẹ̀ju eniyan meje tí wọ́n lè dáhùn ọ̀rọ̀ pẹlu ọgbọ́n lọ.
17 Ẹni tí ó ti ọrùn bọ ìjà tí kì í ṣe tirẹ̀,dàbí ẹni tí ó gbá ajá alájá létí mú.
18 Bíi aṣiwèrè tí ó ju igi iná tabi ọfà olóró,
19 ni ẹni tó ṣi ẹlòmíràn lọ́nà,tí ó wá ń sọ pé “Mo kàn ń ṣeré ni!”
20 Láìsí igi, iná óo kú,bẹ́ẹ̀ ni, láìsí olófòófó, ìjà óo tán.
21 Bí èédú ti rí sí ògúnná, ati igi sí iná,bẹ́ẹ̀ ni oníjà eniyan rí, sí àtidá ìjà sílẹ̀.