24 Ẹni tí ó bá kórìíra eniyan,lè máa fi ọ̀rọ̀ ẹnu bo ara rẹ̀ láṣìírí,ṣugbọn ẹ̀tàn wà ninu rẹ̀,
25 bí ó bá sọ̀rọ̀ dáradára, má ṣe gbà á gbọ́,nítorí ọpọlọpọ ìríra kún inú ọkàn rẹ̀.
26 Ó lè gbìyànjú láti fi ẹ̀tàn pa àrankàn rẹ̀ mọ́,ṣugbọn ìwà burúkú rẹ̀ yóo hàn ní àwùjọ gbogbo eniyan.
27 Ẹni tí ó bá gbẹ́ kòtò, ni yóo já sinu rẹ̀,ẹni tí ó bá sì ń yí òkúta ni òkúta yóo pada yí lù.
28 A-purọ́-mọ́ni a máa kórìíra àwọn tí ń parọ́ mọ́,ẹni tí ń pọ́nni sì lè fa ìparun ẹni.