1 Àwọn eniyan burúkú a máa sá,nígbà tí ẹnikẹ́ni kò lé wọn,ṣugbọn olódodo a máa láyà bíi kinniun.
2 Bí orílẹ̀-èdè kan bá dẹ́ṣẹ̀,léraléra ni wọ́n ó máa jọba,ṣugbọn bí orílẹ̀-èdè kan bá ní àwọn eniyan tí wọn ní òye ati ìmọ̀,yóo wà fún ìgbà pípẹ́.
3 Talaka tí ń ni aláìní láradàbí òjò líle tí ó ba nǹkan ọ̀gbìn jẹ́.
4 Àwọn tí wọ́n kọ òfin sílẹ̀ni wọ́n máa ń yin àwọn eniyan burúkú,ṣugbọn àwọn tí wọn ń pa òfin mọ́ máa ń dojú ìjà kọ wọ́n.
5 Òye ìdájọ́ òdodo kò yé àwọn eniyan burúkú,ṣugbọn ó yé àwọn tí ń wá OLUWA yékéyéké.
6 Talaka tí ń rìn pẹlu òtítọ́ inúsàn ju ọlọ́rọ̀ tí ń hùwà àgàbàgebè lọ.