2 Bí orílẹ̀-èdè kan bá dẹ́ṣẹ̀,léraléra ni wọ́n ó máa jọba,ṣugbọn bí orílẹ̀-èdè kan bá ní àwọn eniyan tí wọn ní òye ati ìmọ̀,yóo wà fún ìgbà pípẹ́.
3 Talaka tí ń ni aláìní láradàbí òjò líle tí ó ba nǹkan ọ̀gbìn jẹ́.
4 Àwọn tí wọ́n kọ òfin sílẹ̀ni wọ́n máa ń yin àwọn eniyan burúkú,ṣugbọn àwọn tí wọn ń pa òfin mọ́ máa ń dojú ìjà kọ wọ́n.
5 Òye ìdájọ́ òdodo kò yé àwọn eniyan burúkú,ṣugbọn ó yé àwọn tí ń wá OLUWA yékéyéké.
6 Talaka tí ń rìn pẹlu òtítọ́ inúsàn ju ọlọ́rọ̀ tí ń hùwà àgàbàgebè lọ.
7 Ọlọ́gbọ́n ọmọ ni ọmọ tí ó pa òfin mọ́,ṣugbọn ẹni tí ń bá àwọn wọ̀bìà rìn, ń dójúti baba rẹ̀.
8 Ẹni tí ó ń fi kún ọrọ̀ rẹ̀ nípa gbígba èléati èrè jíjẹ ní ọ̀nà èrú,ń kó ọrọ̀ náà jọ fún ẹni tí yóo ṣàánú àwọn talaka.