8 Ẹni tí ó ń fi kún ọrọ̀ rẹ̀ nípa gbígba èléati èrè jíjẹ ní ọ̀nà èrú,ń kó ọrọ̀ náà jọ fún ẹni tí yóo ṣàánú àwọn talaka.
9 Ẹni tí ó kọ etí dídi sí òfin Ọlọrun,adura rẹ̀ pàápàá yóo di ìríra sí Ọlọ́run.
10 Ẹni tí ó ṣi olódodo lọ́nà lọ sinu ibi,yóo já sinu kòtò tí òun fúnrarẹ̀ gbẹ́ sílẹ̀,ṣugbọn aláìlẹ́bi eniyan yóo jogún ire.
11 Ọlọ́rọ̀ gbọ́n lójú ara rẹ̀,ṣugbọn talaka tí ó gbọ́n yóo rídìí rẹ̀.
12 Nígbà tí olódodo bá borí, àwọn eniyan á yọ̀ ṣẹ̀ṣẹ̀,ṣugbọn nígbà tí ìkà bá dìde, àwọn eniyan á sá pamọ́.
13 Ẹni tí ó bo ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ mọ́lẹ̀ kò ní ṣe rere,ṣugbọn ẹni tí ó jẹ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀,tí ó sì kọ̀ ọ́ sílẹ̀, yóo rí àánú gbà.
14 Ayọ̀ ń bẹ fún ẹni tí ó ń bẹ̀rù OLUWA nígbà gbogbo,ṣugbọn ẹni tí ó sé ọkàn rẹ̀ le yóo bọ́ sinu ìyọnu.