20 Òmùgọ̀ nírètí ju ẹni tí yóo sọ̀rọ̀ sọ̀rọ̀,tí kò lè kó ara rẹ̀ ní ìjánu lọ.
21 Bí eniyan bá kẹ́ ẹrú ní àkẹ́jù,yóo ya ìyàkuyà níkẹyìn.
22 Ẹni tí inú ń bí a máa dá rògbòdìyàn sílẹ̀,onínúfùfù a sì máa ṣe ọpọlọpọ àṣìṣe.
23 Ìgbéraga eniyan a máa rẹ̀ ẹ́ sílẹ̀,ṣugbọn onírẹ̀lẹ̀ ọkàn yóo gba iyì.
24 Ẹni tí ó ṣe alábàápín pẹlu olè kò fẹ́ràn ẹ̀mí ara rẹ̀,ó gbọ́ ọ̀rọ̀ ègún, ṣugbọn kò sọ fún ẹnikẹ́ni.
25 Ìbẹ̀rù eniyan a máa di ìdẹkùn fún eniyan,ṣugbọn ẹni bá gbẹ́kẹ̀lé OLUWA yóo wà láìléwu.
26 Ọ̀pọ̀ ń wá ojurere olórí,ṣugbọn OLUWA níí dáni ní ẹjọ́ òdodo.