21 Bí eniyan bá kẹ́ ẹrú ní àkẹ́jù,yóo ya ìyàkuyà níkẹyìn.
22 Ẹni tí inú ń bí a máa dá rògbòdìyàn sílẹ̀,onínúfùfù a sì máa ṣe ọpọlọpọ àṣìṣe.
23 Ìgbéraga eniyan a máa rẹ̀ ẹ́ sílẹ̀,ṣugbọn onírẹ̀lẹ̀ ọkàn yóo gba iyì.
24 Ẹni tí ó ṣe alábàápín pẹlu olè kò fẹ́ràn ẹ̀mí ara rẹ̀,ó gbọ́ ọ̀rọ̀ ègún, ṣugbọn kò sọ fún ẹnikẹ́ni.
25 Ìbẹ̀rù eniyan a máa di ìdẹkùn fún eniyan,ṣugbọn ẹni bá gbẹ́kẹ̀lé OLUWA yóo wà láìléwu.
26 Ọ̀pọ̀ ń wá ojurere olórí,ṣugbọn OLUWA níí dáni ní ẹjọ́ òdodo.
27 Olódodo a máa kórìíra alaiṣootọ,eniyan burúkú a sì kórìíra eniyan rere.