5 Ẹni tí ó bá ń pọ́n aládùúgbò rẹ̀,ń dẹ àwọ̀n sílẹ̀ fún ẹsẹ̀ rẹ̀.
6 Eniyan burúkú bọ́ sinu àwọ̀n ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀,ṣugbọn olódodo lè kọrin, ó sì lè máa yọ̀.
7 Olódodo a máa bìkítà fún ẹ̀tọ́ àwọn talaka,ṣugbọn àwọn eniyan burúkú kò ní òye irú rẹ̀.
8 Àwọn ẹlẹ́gàn a máa dá rúkèrúdò sílẹ̀ láàrin ìlú,ṣugbọn àwọn ọlọ́gbọ́n a máa paná ibinu.
9 Nígbà tí ọlọ́gbọ́n bá pe òmùgọ̀ lẹ́jọ́,ẹ̀rín ni òmùgọ̀ yóo máa fi rín,yóo máa pariwo, kò sì ní dákẹ́.
10 Àwọn apànìyàn kórìíra olóòótọ́ inú,wọ́n sì ń wá ọ̀nà láti pa á.
11 Òmùgọ̀ eniyan a máa bínú,ṣugbọn ọlọ́gbọ́n a máa mú sùúrù.