13 Ayọ̀ ń bẹ fún ẹni tí ó wá ọgbọ́n rí,ati ẹni tí ó ní òye.
14 Nítorí èrè rẹ̀ dáraju èrè orí fadaka ati ti wúrà lọ.
15 Ọgbọ́n níye lóríó ju ohun ọ̀ṣọ́ olówó iyebíye lọ,kò sí ohun tí o lè fi wé e,ninu gbogbo ohun tí ọkàn rẹ lè fẹ́.
16 Ẹ̀mí gígùn wà ní ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀,ọrọ̀ ati iyì sì wà ní ọwọ́ òsì rẹ̀.
17 Ọ̀nà rẹ̀ tura pupọ,alaafia sì ni gbogbo ọ̀nà rẹ̀.
18 Igi ìyè ni fún àwọn tí wọ́n rọ̀ mọ́ ọn,ayọ̀ sì ń bẹ fún àwọn tí wọ́n dì í mú ṣinṣin.
19 Ọgbọ́n ni OLUWA fi fi ìdí ayé sọlẹ̀,òye ni ó sì fi dá ọ̀run.