19 Ọgbọ́n ni OLUWA fi fi ìdí ayé sọlẹ̀,òye ni ó sì fi dá ọ̀run.
20 Nípa ìmọ̀ rẹ̀ ni ibú fi ń tú omi jáde,tí ìrì fi ń sẹ̀ láti inú ìkùukùu.
21 Ọmọ mi, di ọgbọ́n tí ó yè kooro ati làákàyè mú,má sì ṣe jẹ́ kí wọn bọ́ kúrò lọ́wọ́ rẹ,
22 wọ́n yóo jẹ́ ìyè fún ẹ̀mí rẹ,ati ohun ọ̀ṣọ́ ní ọrùn rẹ.
23 Nígbà náà ni o óo máa rìnláìléwu ati láìkọsẹ̀.
24 Bí o bá jókòó, ẹ̀rù kò ní bà ọ́,bí o bá sùn, oorun yóo máa dùn mọ́ ọ.
25 Má bẹ̀rù àjálù òjijì,tabi ìparun àwọn ẹni ibi,nígbà tí ó bá dé bá ọ,