25 Má bẹ̀rù àjálù òjijì,tabi ìparun àwọn ẹni ibi,nígbà tí ó bá dé bá ọ,
26 nítorí pé, OLUWA ni igbẹkẹle rẹ,kò sì ní jẹ́ kí o ti ẹsẹ̀ bọ tàkúté.
27 Má ṣe fa ọwọ́ ire sẹ́yìn lọ́dọ̀ àwọn tí ó tọ́ sí, nígbà tí ó bá wà ní ìkáwọ́ rẹ láti ṣe é.
28 Má sọ fún aládùúgbò rẹ pé,“Máa lọ ná, n óo fún ọ tí o bá pada wá lọ́la,”nígbà tí ohun tí ó fẹ́ wà lọ́dọ̀ rẹ.
29 Má ṣe gbèrò ibi sí aládùúgbò rẹtí ń fi inú kan bá ọ gbé.
30 Má ṣe bá ẹnikẹ́ni jà láìnídìí,nígbà tí kò ṣe ọ́ níbi.
31 Má ṣe ìlara ẹni ibimá sì ṣe tẹ̀ sí èyíkéyìí ninu àwọn ọ̀nà rẹ̀.