29 Má ṣe gbèrò ibi sí aládùúgbò rẹtí ń fi inú kan bá ọ gbé.
30 Má ṣe bá ẹnikẹ́ni jà láìnídìí,nígbà tí kò ṣe ọ́ níbi.
31 Má ṣe ìlara ẹni ibimá sì ṣe tẹ̀ sí èyíkéyìí ninu àwọn ọ̀nà rẹ̀.
32 Nítorí OLUWA kórìíra alárèékérekè,ṣugbọn ó ní igbẹkẹle ninu àwọn tí wọn dúró ṣinṣin.
33 Ègún OLUWA wà lórí ìdílé ẹni ibi,ṣugbọn a máa bukun ibùgbé àwọn olódodo.
34 A máa fi àwọn pẹ̀gànpẹ̀gàn ṣe ẹlẹ́yà, ṣugbọn a máa fi ojurere wo àwọn onírẹ̀lẹ̀.
35 Ọlọ́gbọ́n yóo jogún iyì,ṣugbọn ojú yóo ti òmùgọ̀.