7 Má ṣe jẹ́ ọlọ́gbọ́n lójú ara rẹ, bẹ̀rù OLUWA, kí o sì yẹra fún ibi.
8 Tí o bá ṣe bẹ́ẹ̀, yóo jẹ́ ìwòsàn fún ara rẹ,ati ìtura fún egungun rẹ.
9 Fi ohun ìní rẹ bọ̀wọ̀ fún OLUWApẹlu gbogbo àkọ́so oko rẹ.
10 Nígbà náà ni àká rẹ yóo kún bámúbámú,ìkòkò waini rẹ yóo sì kún àkúnya.
11 Ọmọ mi, má ṣe kẹ́gàn ìtọ́ni OLUWA, má sì ṣe jẹ́ kí ìbáwí rẹ̀ sú ọ.
12 Nítorí ẹni tí OLUWA bá fẹ́ níí báwí gẹ́gẹ́ bí baba tí máa ń bá ọmọ rẹ̀ tí ó bá fẹ́ràn wí.
13 Ayọ̀ ń bẹ fún ẹni tí ó wá ọgbọ́n rí,ati ẹni tí ó ní òye.