1 Ọmọ mi fetí sí ọgbọ́n tí mò ń kọ́ ọ,tẹ́tí rẹ sí òye mi,
2 kí o baà lè ní làákàyè,kí ọ̀rọ̀ ẹnu rẹ lè kún fún ìmọ̀.
3 Nítorí ẹnu alágbèrè obinrin a máa dùn bí oyin,ọ̀rọ̀ rẹ̀ sì tuni lára ju òróró lọ,
4 ṣugbọn níkẹyìn ọ̀rọ̀ rẹ̀ á korò bí iwọ,ẹnu rẹ̀ á sì mú bí idà olójú meji.
5 Ẹsẹ̀ rẹ̀ ń dà gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ lọ sinu ikú,ìgbésẹ̀ rẹ̀ sì lọ tààrà sinu ibojì.