11 Kí o má baà kérora nígbẹ̀yìn ayé rẹ,nígbà tí o bá di ìjẹ fún ẹni ẹlẹ́ni
12 nígbà náà ni o óo wí pé,“Kí ló dé tí mo kórìíra ìtọ́ni,tí ọkàn mi sì kẹ́gàn ìbáwí!
13 N kò fetí sí ọ̀rọ̀ àwọn olùkọ́ min kò sì gba ti àwọn tí wọn ń tọ́ mi sọ́nà.
14 Èyí ni ó sún mi dé etí bèbè ìparun,láàrin àwùjọ eniyan.”
15 Ìwọ ọkọ, láti inú àmù rẹ ni kí o ti máa mu omi;omi tí ń sun láti inú kànga rẹ ni kí o máa mu.
16 Kò dára kí orísun rẹ máa ṣàn káàkiri,bí omi àgbàrá ní gbogbo òpópónà.
17 Tìrẹ nìkan ṣoṣo ni kí ó jẹ́,má jẹ́ kí àjèjì bá ọ pín ninu rẹ̀.