6 Ó kọ̀ láti rin ọ̀nà ìyè,ọ̀nà rẹ̀ wọ́, kò sì mọ̀.
7 Nisinsinyii, ẹ̀yin ọmọ mi, ẹ gbọ́ ọ̀rọ̀ mi,ẹ má sì kọ ọ̀rọ̀ sí mi lẹ́nu.
8 Ẹ jìnnà sí alágbèrè obinrin,kí ẹ má tilẹ̀ súnmọ́ ẹnu ọ̀nà rẹ̀,
9 kí ẹ má baà gbé ògo yín fún ẹlòmíràn,kí ẹ sì fi ìgbé ayé yín lé aláìláàánú lọ́wọ́.
10 Kí àjèjì má baà jèrè iṣẹ́ yín,kí làálàá rẹ má sì bọ́ sápò àlejò.
11 Kí o má baà kérora nígbẹ̀yìn ayé rẹ,nígbà tí o bá di ìjẹ fún ẹni ẹlẹ́ni
12 nígbà náà ni o óo wí pé,“Kí ló dé tí mo kórìíra ìtọ́ni,tí ọkàn mi sì kẹ́gàn ìbáwí!