11 yóo jẹ́ kí òṣì dé bá ọ, bí ọlọ́ṣà dé bá eniyan. Àìní yóo sì dé bá ọ bíi jagunjagun dé báni.
12 Eniyan lásán, ìkà eniyan, a máa rìn káàkiri,a máa sọ̀rọ̀ àrékérekè,
13 bí ó ti ń ṣẹ́jú, bẹ́ẹ̀ ni ó ń jansẹ̀ mọ́lẹ̀,tí ó sì ń fi ìka ṣe àpèjúwe.
14 Ó ń fi inú burúkú pète ibi, ó sì ń fi ojoojumọ dá ìjà sílẹ̀,
15 nítorí náà, ibi yóo dé bá a lójijì,yóo parun kíá láìsí àtúnṣe.
16 Àwọn nǹkan mẹfa kan wà tí OLUWA kò fẹ́:wọ́n tilẹ̀ tó meje tí ó jẹ́ ohun ìríra fún un:
17 Ìgbéraga, irọ́ pípa,ẹni tí ń déédé pa aláìṣẹ̀,