15 nítorí náà, ibi yóo dé bá a lójijì,yóo parun kíá láìsí àtúnṣe.
16 Àwọn nǹkan mẹfa kan wà tí OLUWA kò fẹ́:wọ́n tilẹ̀ tó meje tí ó jẹ́ ohun ìríra fún un:
17 Ìgbéraga, irọ́ pípa,ẹni tí ń déédé pa aláìṣẹ̀,
18 ọkàn tí ń pète ìkà,ẹsẹ̀ tí ń sáré sí ibi,
19 ẹlẹ́rìí èké tí ẹnu rẹ̀ kún fún irọ́,ati ẹni tí ń dá ìjà sílẹ̀ láàrin eniyan.
20 Ọmọ mi, pa òfin baba rẹ mọ́,má sì ṣe kọ ẹ̀kọ́ ìyá rẹ sílẹ̀.
21 Fi wọ́n sọ́kàn nígbà gbogbo,kí o sì so wọ́n mọ́ ọrùn rẹ.