2 tí o bá bọ́ sinu tàkútétí o fi ọ̀rọ̀ ẹnu rẹ dẹ fún ara rẹ,tí ọ̀rọ̀ ẹnu rẹ sì ti kó bá ọ,
3 o ti bọ́ sọ́wọ́ aládùúgbò rẹ.Nítorí náà báyìí ni kí o ṣe, ọmọ mi,kí o lè gba ara rẹ là:lọ bá a kíákíá, kí o sì bẹ̀ ẹ́.
4 Má sùn,má sì tòògbé,
5 gba ara rẹ sílẹ̀ bí àgbọ̀nrín tíí gba ara rẹ̀ sílẹ̀ lọ́wọ́ ọdẹ,àní, bí ẹyẹ tíí ṣe, tíí fi í bọ́ lọ́wọ́ pẹyẹpẹyẹ.
6 Ìwọ ọ̀lẹ, tọ èèrùn lọ,ṣàkíyèsí ìṣe rẹ̀, kí o sì kọ́gbọ́n.
7 Ẹ̀dá tí kò ní olórí, tabi alabojuto, tabi aláṣẹ
8 sibẹsibẹ, a máa tọ́jú oúnjẹ rẹ̀ ní àkókò ẹ̀ẹ̀rùn;a sì máa kó oúnjẹ jọ, ní àkókò ìkórè.