18 Wá, jẹ́ kí á ṣeré ìfẹ́títí ilẹ̀ yóo fi mọ́,jẹ́ kí á fi ìfẹ́ gbádùn ara wa.
19 Ọkọ mi kò sí nílé,ó ti lọ sí ìrìn àjò, ọ̀nà rẹ̀ sì jìn.
20 Ó mú owó pupọ lọ́wọ́,kò ní dé títí òṣùpá yóo fi di àrànmọ́jú.”
21 Ó rọ̀ ọ́ pẹlu ọpọlọpọ ọ̀rọ̀ ẹ̀tàn,ó fi ọ̀rọ̀ dídùn mú un.
22 Lẹsẹkẹsẹ, ọmọkunrin náà bẹ̀rẹ̀ sí tẹ̀lé e,bíi mààlúù tí wọn ń fà lọ pa,tabi bí àgbọ̀nrín tí ó tẹsẹ̀ bọ tàkúté,
23 títí tí ọfà fi wọ̀ ọ́ ninubí ẹyẹ tí ń yára bọ́ sinu okùn,láì mọ̀ pé ó lè ṣe ikú pa òun.
24 Nisinsinyii, ẹ fetí sílẹ̀, ẹ̀yin ọmọ mi,ẹ farabalẹ̀ gbọ́ nǹkan tí mò ń sọ.