20 Ó mú owó pupọ lọ́wọ́,kò ní dé títí òṣùpá yóo fi di àrànmọ́jú.”
21 Ó rọ̀ ọ́ pẹlu ọpọlọpọ ọ̀rọ̀ ẹ̀tàn,ó fi ọ̀rọ̀ dídùn mú un.
22 Lẹsẹkẹsẹ, ọmọkunrin náà bẹ̀rẹ̀ sí tẹ̀lé e,bíi mààlúù tí wọn ń fà lọ pa,tabi bí àgbọ̀nrín tí ó tẹsẹ̀ bọ tàkúté,
23 títí tí ọfà fi wọ̀ ọ́ ninubí ẹyẹ tí ń yára bọ́ sinu okùn,láì mọ̀ pé ó lè ṣe ikú pa òun.
24 Nisinsinyii, ẹ fetí sílẹ̀, ẹ̀yin ọmọ mi,ẹ farabalẹ̀ gbọ́ nǹkan tí mò ń sọ.
25 Ẹ má jẹ́ kí ọkàn yín lọ sọ́dọ̀ irú obinrin bẹ́ẹ̀,ẹ má ṣèèṣì yà sí ọ̀dọ̀ rẹ̀.
26 Ọ̀pọ̀ ni àwọn tí ó ti sọ di ẹni ilẹ̀,ọpọlọpọ àwọn alágbára ni ó ti ṣe ikú pa.