4 Sọ fún ọgbọ́n pé, “Ìwọ ni arabinrin mi,”kí o sì pe ìmọ̀ ní ọ̀rẹ́ kòríkòsùn rẹ,
5 kí wọ́n baà lè pa ọ́ mọ́,kúrò lọ́dọ̀ alágbèrè obinrin,ati kúrò lọ́wọ́ onírìnkurìn pẹlu ọ̀rọ̀ dídùn rẹ̀.
6 Mo yọjú wo ìta,láti ojú fèrèsé ilé mi.
7 Mo rí àwọn ọ̀dọ́ tí wọn kò ní ìrírí,mo ṣe akiyesi pé láàrin wọn,ọmọkunrin kan wà tí kò gbọ́n.
8 Ó ń lọ ní òpópónà, lẹ́bàá kọ̀rọ̀ ilé alágbèrè obinrin náà,
9 ní àṣáálẹ́, nígbà tí ọjọ́ ń pofírí,tí ilẹ̀ ti ń ṣú, tí òkùnkùn ti ń kùn.
10 Obinrin kan lọ pàdé rẹ̀,ó wọ aṣọ aṣẹ́wó,ọkàn rẹ̀ kún fún ẹ̀tàn.