6 Mo yọjú wo ìta,láti ojú fèrèsé ilé mi.
7 Mo rí àwọn ọ̀dọ́ tí wọn kò ní ìrírí,mo ṣe akiyesi pé láàrin wọn,ọmọkunrin kan wà tí kò gbọ́n.
8 Ó ń lọ ní òpópónà, lẹ́bàá kọ̀rọ̀ ilé alágbèrè obinrin náà,
9 ní àṣáálẹ́, nígbà tí ọjọ́ ń pofírí,tí ilẹ̀ ti ń ṣú, tí òkùnkùn ti ń kùn.
10 Obinrin kan lọ pàdé rẹ̀,ó wọ aṣọ aṣẹ́wó,ọkàn rẹ̀ kún fún ẹ̀tàn.
11 Ó jẹ́ aláriwo ati onírìnkurìn obinrin,kì í gbélé rẹ̀.
12 Bí ó ti ń rìn kiri lójú pópó,bẹ́ẹ̀ ni yóo máa lọ, tí yóo máa bọ̀ láàrin ọjà,yóo máa dọdẹ kiri ní gbogbo kọ̀rọ̀.