1 Ọgbọ́n ti kọ́lé,ó ti gbé àwọn òpó rẹ̀ mejeeje nàró.
2 Ó ti pa ẹran rẹ̀,ó ti pọn ọtí waini rẹ̀,ó sì ti tẹ́ tabili rẹ̀ kalẹ̀.
3 Ó ti rán àwọn iranṣẹbinrin rẹ̀kí wọn lọ máa kígbe lórí àwọn òkè láàrin ìlú pé:
4 “Ẹ yà síbí ẹ̀yin òpè!”Ó sọ fún ẹni tí kò lọ́gbọ́n pé,
5 “Máa bọ̀, wá jẹ lára oúnjẹ mi,kí o sì mu ninu ọtí waini tí mo ti pò.
6 Fi àìmọ̀kan sílẹ̀, kí o sì yè,kí o máa rin ọ̀nà làákàyè.”
7 Ẹni tí ń tọ́ oníyẹ̀yẹ́ eniyan sọ́nà fẹ́ kan àbùkù,ẹni tí ń bá ìkà eniyan wí ń wá ìfarapa fún ara rẹ̀.