1 Rehoboamu lọ sí Ṣekemu, nítorí pé gbogbo Israẹli ti péjọ sibẹ láti fi jọba.
2 Nígbà tí Jeroboamu, ọmọ Nebati, gbọ́, ó pada wá láti Ijipti, níbi tí ó ti sá lọ fún Solomoni.
3 Àwọn ọmọ Israẹli ni wọ́n ranṣẹ sí i, òun ati gbogbo àwọn ọmọ Israẹli lọ sọ́dọ̀ Rehoboamu, wọ́n wí fún un pé,
4 “Àjàgà tí baba rẹ gbé bọ̀ wá lọ́rùn wúwo, ṣugbọn nisinsinyii, dín wahala tí baba rẹ fi wá ṣe kù, kí o sì sọ àjàgà wa di fúfúyẹ́, a óo sì máa sìn ọ́.”
5 Rehoboamu bá dáhùn pé, “Ẹ pada wá gbọ́ èsì lẹ́yìn ọjọ́ mẹta.” Àwọn eniyan náà bá lọ.
6 Rehoboamu bá lọ jíròrò pẹlu àwọn àgbààgbà Israẹli tí wọ́n bá baba rẹ̀ ṣiṣẹ́ nígbà ayé rẹ̀, ó ní, “Ẹ fún mi ní ìmọ̀ràn, irú èsì wo ni ó yẹ kí n fún àwọn eniyan wọnyi?”
7 Wọ́n gbà á ní ìmọ̀ràn pé, “Bí o bá ṣe dáradára sí àwọn eniyan wọnyi, tí o bá ṣe ohun tí ó tẹ́ wọn lọ́rùn, tí o sì sọ̀rọ̀ dáradára fún wọn, wọn yóo máa sìn ọ́ títí lae.”