1 Nígbà tí Rehoboamu dé Jerusalẹmu, ó kó ọ̀kẹ́ mẹsan-an (180,000) àwọn akọni ọmọ ogun jọ láti inú ẹ̀yà Juda ati Bẹnjamini, láti bá àwọn ọmọ Israẹli jagun, kí ó lè fi ipá gba ìjọba rẹ̀ pada.
2 Ṣugbọn OLUWA sọ fún wolii Ṣemaaya, eniyan Ọlọrun pé,
3 “Sọ fún Rehoboamu ọmọ Solomoni, ọba Juda, ati gbogbo àwọn ọmọ Israẹli tí wọn ń gbé Juda ati Bẹnjamini pé,
4 OLUWA ní, ‘Ẹ kò gbọdọ̀ lọ bá àwọn arakunrin yín jà. Kí olukuluku yín pada sí ilé rẹ̀ nítorí èmi ni mo jẹ́ kí ọ̀rọ̀ yìí ó ṣẹlẹ̀.’ ” Wọ́n gbọ́ràn sí OLUWA lẹ́nu, wọ́n pada, wọn kò sì lọ bá Jeroboamu jagun mọ́.
5 Rehoboamu ń gbé Jerusalẹmu, ó kọ́ àwọn ìlú ààbò wọnyi sí Juda:
6 Bẹtilẹhẹmu, Etamu, ati Tekoa;
7 Betisuri, Soko, ati Adulamu;
8 Gati, Mareṣa, ati Sifi;
9 Adoraimu, Lakiṣi, ati Aseka;
10 Sora, Aijaloni ati Heburoni. Àwọn ni ìlú olódi ní Juda ati Bẹnjamini.
11 Ó tún àwọn ìlú olódi ṣe, wọ́n lágbára, níbẹ̀ ni ó fi àwọn olórí ogun sí, ó sì kó ọpọlọpọ oúnjẹ, epo ati ọtí waini pamọ́ sibẹ.
12 Ó kó ọ̀kọ̀ ati apata sinu gbogbo wọn, ó sì fi agbára kún agbára wọn. Bẹ́ẹ̀ ló ṣe fi ọwọ́ mú Juda ati Bẹnjamini.
13 Àwọn alufaa ati àwọn ọmọ Lefi tí wọ́n wà ní gbogbo ilẹ̀ Israẹli sì fara mọ́ Rehoboamu. Gbogbo wọn bẹ̀rẹ̀ sí wọ́ lọ sọ́dọ̀ rẹ̀.
14 Àwọn ọmọ Lefi fi ilẹ̀ wọn sílẹ̀ ati ẹran ọ̀sìn wọn ati gbogbo ohun ìní wọn, wọ́n kó wá sí Juda, ati Jerusalẹmu; nítorí pé Jeroboamu ati àwọn ọmọ rẹ̀ lé wọn jáde, wọn kò jẹ́ kí wọ́n ṣe iṣẹ́ wọn gẹ́gẹ́ bí alufaa Ọlọrun.
15 Ó yan àwọn alufaa ti ara rẹ̀ fún ibi ìrúbọ ati fún ilé ère ewúrẹ́ ati ti ọmọ aguntan tí ó gbé kalẹ̀.
16 Gbogbo àwọn tí wọ́n fẹ́ sin Ọlọrun Israẹli tọkàntọkàn láti inú olukuluku ẹ̀yà Israẹli, tẹ̀lé àwọn alufaa wá sí Jerusalẹmu láti ṣe ìrúbọ sí OLUWA Ọlọrun àwọn baba wọn.
17 Wọ́n sọ ìjọba Juda di alágbára, wọ́n sì ṣe alátìlẹ́yìn fún Rehoboamu ọmọ Solomoni fún ọdún mẹta; wọ́n ń rìn ní ìlànà Dafidi ati ti Solomoni ní gbogbo ìgbà náà.
18 Rehoboamu fẹ́ Mahalati, ọmọ Jerimotu, ọmọ Dafidi, ìyá rẹ̀ ni Abihaili, ọmọ Eliabu, ọmọ Jese.
19 Iyawo Rehoboamu yìí bí ọmọkunrin mẹta fún un; wọ́n ń jẹ́: Jeuṣi, Ṣemaraya ati Sahamu.
20 Lẹ́yìn náà, ó tún fẹ́ Maaka, ọmọ Absalomu; òun bí ọmọkunrin mẹrin fún un; wọ́n ń jẹ́ Abija, Atai, Sisa ati Ṣelomiti.
21 Maaka, ọmọ Absalomu ni Rehoboamu fẹ́ràn jùlọ ninu àwọn iyawo rẹ̀. Àwọn mejidinlogun ni ó gbé ní iyawo, o sì ní ọgọta obinrin mìíràn. Ó bí ọmọkunrin mejidinlọgbọn ati ọgọta ọmọbinrin.
22 Ó fẹ́ràn ọmọ rẹ̀ tí ń jẹ́ Abija ju gbogbo àwọn ọmọ rẹ̀ yòókù lọ. Ó yàn án láti jẹ́ ọba lẹ́yìn tí òun bá kú.
23 Ó dọ́gbọ́n fi àwọn ọmọ rẹ̀ ṣe olórí káàkiri, ó pín wọn káàkiri jákèjádò ilẹ̀ Juda ati Bẹnjamini ní àwọn ìlú alágbára. Ó fún wọn ní ohun tí wọ́n ṣe aláìní. Ó sì fẹ́ iyawo fún gbogbo wọn.