Kronika Keji 35 BM

Josaya Pa Àjọ Ìrékọjá Mọ́

1 Josaya ṣe Àjọ Ìrékọjá fún OLUWA ní Jerusalẹmu. Ní ọjọ́ kẹrinla, oṣù kinni ni wọ́n pa ọ̀dọ́ aguntan Àjọ Ìrékọjá.

2 Ó yan àwọn alufaa sí ipò wọn, ó sì gbà wọ́n níyànjú kí wọ́n ṣe iṣẹ́ wọn ninu ilé OLUWA.

3 Ó sọ fún àwọn ọmọ Lefi tí wọn ń kọ́ àwọn ọmọ Israẹli, tí wọ́n sì jẹ́ mímọ́ pé, “Ẹ gbé Àpótí mímọ́ náà sinu ilé tí Solomoni ọmọ Dafidi, ọba Israẹli kọ́. Ẹ kò ní máa gbé e lé èjìká kiri mọ́. Ṣugbọn kí ẹ máa ṣiṣẹ́ fún OLUWA Ọlọrun, ati fún gbogbo eniyan Israẹli.

4 Ẹ kó ara yín jọ ní ìdílé ìdílé ati ní ọ̀wọ̀ọ̀wọ́ gẹ́gẹ́ bí ìlànà Dafidi, ọba Israẹli ati ti Solomoni ọmọ rẹ̀.

5 Ẹ dúró ní ibi mímọ́, kí ẹ sì pín ara yín sí ìsọ̀rí-ìsọ̀rí gẹ́gẹ́ bí iye ìdílé àwọn arakunrin yín. Ìdílé kọ̀ọ̀kan gbọdọ̀ ní àwọn ọmọ Lefi tí wọn yóo wà pẹlu wọn.

6 Kí ẹ pa ọ̀dọ́ aguntan Ìrékọjá, kí ẹ ya ara yín sí mímọ́, kí ẹ múra sílẹ̀ fún àwọn arakunrin yín láti ṣe ohun tí OLUWA sọ láti ẹnu Mose.”

7 Josaya ọba fún gbogbo àwọn tí wọ́n wà níbẹ̀ ní ẹran fún ẹbọ Ìrékọjá. Láti inú agbo ẹran tirẹ̀ ni ó ti mú ẹgbaa mẹẹdogun (30,000) aguntan ati ọmọ ewúrẹ́, ati ẹgbẹẹdogun (3,000) mààlúù fún wọn.

8 Àwọn olóyè náà fi tọkàntọkàn fún àwọn eniyan, ati àwọn alufaa ati àwọn ọmọ Lefi ní nǹkan. Hilikaya, Sakaraya ati Jehieli, àwọn alákòóso ninu ilé Ọlọrun, fún àwọn alufaa ní ẹgbẹtala (2,600) ọ̀dọ́ aguntan ati ọmọ ewúrẹ́ ati ọọdunrun (300) mààlúù fún ẹbọ Ìrékọjá.

9 Àwọn olórí ninu àwọn ọmọ Lefi: Konanaya pẹlu Ṣemaaya ati Netaneli, àwọn arakunrin rẹ̀; ati Haṣabaya, Jeieli, ati Josabadi, àwọn olóyè ninu ọmọ Lefi dá ẹẹdẹgbaata (5,000) ọ̀dọ́ aguntan, ati ọmọ ewúrẹ́, ati ẹẹdẹgbẹta (500) mààlúù fún àwọn ọmọ Lefi kí wọn fi rú ẹbọ Ìrékọjá.

10 Nígbà tí gbogbo ètò ti parí, àwọn alufaa ati àwọn ọmọ Lefi dúró ní ààyè wọn gẹ́gẹ́ bí àṣẹ tí ọba pa.

11 Wọ́n pa ọ̀dọ́ aguntan Ìrékọjá, àwọn alufaa wọ́n ẹ̀jẹ̀ tí wọ́n gbà lára àwọn ẹran náà sórí pẹpẹ, àwọn ọmọ Lefi sì bó awọ àwọn ẹran náà.

12 Wọ́n ya ẹbọ sísun sọ́tọ̀ kí wọ́n lè pín wọn fún gbogbo ìdílé tí ó wà níbẹ̀, kí wọ́n lè fi rúbọ sí OLUWA gẹ́gẹ́ bí a ti kọ ọ́ sinu ìwé Mose. Bẹ́ẹ̀ náà ni wọ́n ṣe pẹlu àwọn mààlúù.

13 Wọ́n sun ọ̀dọ́ aguntan Ìrékọjá gẹ́gẹ́ bí ìlànà. Wọ́n bọ ẹran ẹbọ mímọ́ ninu ìkòkò, ìsaasùn ati apẹ, wọ́n sì pín in fún àwọn eniyan lẹsẹkẹsẹ.

14 Lẹ́yìn náà, wọ́n tọ́jú tiwọn ati ti àwọn alufaa, àwọn ọmọ Aaroni. Nítorí iṣẹ́ ṣíṣe kò jẹ́ kí àwọn alufaa rí ààyè, láti àárọ̀ títí di alẹ́. Wọ́n ń rú ẹbọ sísun, wọ́n sì ń sun ọ̀rá ẹran níná. Nítorí náà ni àwọn ọmọ Lefi fi tọ́jú tiwọn, tí wọ́n sì tọ́jú ti àwọn alufaa, àwọn ọmọ Aaroni.

15 Àwọn akọrin tí wọ́n jẹ́ ọmọ Asafu dúró ní ipò wọn gẹ́gẹ́ bí àṣẹ Dafidi. Bẹ́ẹ̀ náà ni Asafu, Hemani, ati Jedutuni, aríran ọba. Àwọn aṣọ́nà tẹmpili kò kúrò ní ààyè wọn, nítorí pé àwọn ọmọ Lefi ti tọ́jú ẹbọ ìrékọjá tiwọn fún wọn.

16 Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n ṣe ìsìn Àjọ Ìrékọjá ati ti ẹbọ sísun lórí pẹpẹ OLUWA ní ọjọ́ náà gẹ́gẹ́ bí àṣẹ Josaya ọba.

17 Àwọn ọmọ Israẹli tí wọ́n wá ṣe àsè Àjọ Ìrékọjá, wọ́n sì ṣe Àjọ Àìwúkàrà fún ọjọ́ meje.

18 Kò tíì sí irú àsè Àjọ Ìrékọjá bẹ́ẹ̀ ní gbogbo ilẹ̀ Israẹli láti ìgbà ayé wolii Samuẹli. Kò sì tíì sí ọba kankan ní Israẹli tí ó tíì ṣe àsè Àjọ Ìrékọjá bí Josaya ti ṣe pẹlu àwọn alufaa, àwọn ọmọ Lefi, àwọn eniyan Juda, àwọn tí wọ́n wá láti Israẹli ati àwọn ará Jerusalẹmu.

19 Ní ọdún kejidinlogun ìjọba Josaya ni wọ́n ṣe Àjọ Ìrékọjá yìí.

Ìgbẹ̀yìn Ìjọba Josaya

20 Nígbà tí ó yá lẹ́yìn tí Josaya ti ṣe ètò inú tẹmpili tán, Neko, ọba Ijipti wá jagun ní Kakemiṣi, ní odò Yufurate. Josaya sì digun lọ bá a jà.

21 Neko rán ikọ̀ sí Josaya pé, “Kí ló lè fa ìjà láàrin wa, ìwọ ọba Juda? Ìwọ kọ́ ni mo wá bá jà lákòókò yìí, orílẹ̀-èdè tí èmi pẹlu rẹ̀ ní ìjà ni mo wá bá jà. Ọlọrun ni ó sì sọ fún mi pé kí n má jáfara, má ṣe dojú ìjà kọ Ọlọrun, nítorí pé ó wà pẹlu mi; kí ó má ba à pa ọ́ run.”

22 Ṣugbọn Josaya ṣe oríkunkun, ó paradà kí wọ́n má baà dá a mọ̀, ó lọ bá a jà. Kò fetí sí ọ̀rọ̀ Neko, tí Ọlọrun sọ, ó lọ bá Neko jà ní pẹ̀tẹ́lẹ̀ Megido.

23 Àwọn tafàtafà ta Josaya ọba ní ọfà, ó bá pe àwọn iranṣẹ rẹ̀, ó sì sọ fún wọn pé, “Ẹ gbé mi kúrò lójú ogun, nítorí mo ti fara gbọgbẹ́, ọgbẹ́ náà sì pọ̀.”

24 Nítorí náà, wọ́n gbé e kúrò ninu kẹ̀kẹ́ ogun tí ó wà tẹ́lẹ̀ sinu òmíràn, wọ́n sì gbé e lọ sí Jerusalẹmu. Ó kú, wọ́n sì sin ín sí ibojì àwọn baba rẹ̀. Gbogbo Juda ati Jerusalẹmu ṣe ọ̀fọ̀ rẹ̀.

25 Wolii Jeremaya kọ orin arò fún Josaya ọba. Ó ti di àṣà ní Israẹli fún àwọn akọrin, lọkunrin ati lobinrin láti máa mẹ́nu ba Josaya nígbàkúùgbà tí wọ́n bá ń kọrin arò.

26 Àkọsílẹ̀ gbogbo àwọn nǹkan yòókù tí Josaya ṣe ati iṣẹ́ rere rẹ̀, gẹ́gẹ́ bí a ti kọ ọ́ sinu ìwé òfin OLUWA,

27 gbogbo ohun tí ó ṣe láti ìbẹ̀rẹ̀ dé òpin, wà ninu Ìwé Ìtàn Àwọn Ọba Israẹli ati ti Juda.

orí

1 2 3 4 5 6 7 8 9 10 11 12 13 14 15 16 17 18 19 20 21 22 23 24 25 26 27 28 29 30 31 32 33 34 35 36