Kronika Keji 8 BM

Àwọn Àsẹyọrí Solomoni

1 Ó gba Solomoni ní ogún ọdún láti kọ́ tẹmpili OLUWA ati ààfin tirẹ̀.

2 Lẹ́yìn náà, ó tún àwọn ìlú tí Huramu ọba, fún un kọ́, ó sì fi àwọn ọmọ Israẹli sibẹ.

3 Ó lọ gbógun ti ìlú Hamati ati Soba, ó sì ṣẹgun wọn.

4 Ó kọ́ ìlú Tadimori ní aṣálẹ̀, ati gbogbo ìlú tí wọn ń kó ìṣúra jọ sí ní Hamati.

5 Ó kọ́ ìlú Beti Horoni ti òkè ati Beti Horoni ti ìsàlẹ̀. Wọ́n jẹ́ ìlú olódi, wọ́n ní ìlẹ̀kùn ati ọ̀pá ìdábùú ìlẹ̀kùn,

6 bẹ́ẹ̀ sì ni ìlú Baalati ati gbogbo ìlú tí wọn ń kó ìṣúra pamọ́ sí, ati àwọn ìlú tí àwọn kẹ̀kẹ́ ogun rẹ̀ wà, ati ìlú fún àwọn ẹlẹ́ṣin, ati gbogbo ohun tí ó pinnu lọ́kàn rẹ̀ láti kọ́ ní Jerusalẹmu, ati ní Lẹbanoni, ati ní gbogbo ibi tí ìjọba rẹ̀ dé.

7 Gbogbo àwọn eniyan tí wọ́n kù ní ilẹ̀ náà lára àwọn ará Hiti, ati àwọn ará Amori, àwọn ará Perisi, àwọn ará Hifi ati àwọn ará Jebusi, tí wọn kì í ṣe ọmọ Israẹli,

8 gbogbo ìran àwọn tí ó kù ní ilẹ̀ náà, tí àwọn ọmọ Israẹli kò parun, ni Solomoni ń fi tipátipá kó ṣiṣẹ́ títí di òní olónìí.

9 Ṣugbọn kò fi ipá kó àwọn ọmọ Israẹli ṣiṣẹ́ bí ẹrú, ṣugbọn ó ń lò wọ́n bíi jagunjagun, òṣìṣẹ́ ìjọba, balogun kẹ̀kẹ́ ogun, ati àwọn ẹlẹ́ṣin rẹ̀.

10 Àwọn olórí lára àwọn òṣìṣẹ́ Solomoni jẹ́ igba ati aadọta (250), àwọn ni wọ́n ń ṣe àkóso àwọn tí wọn ń ṣiṣẹ́.

11 Solomoni mú iyawo rẹ̀, ọmọ Farao kúrò ní ìlú Dafidi, lọ sí ibi tí ó kọ́ fún un. Ó ní, “Iyawo mi kò gbọdọ̀ máa gbé ààfin Dafidi, ọba Israẹli; nítorí pé ibikíbi tí àpótí OLUWA bá ti wọ̀, ó ti di ibi mímọ́.”

12 Solomoni rú ẹbọ sísun sí OLUWA lórí pẹpẹ OLUWA tí ó kọ́ siwaju yàrá àbáwọlé ní tẹmpili.

13 Ó ń rú ẹbọ sísun gẹ́gẹ́ bí ìlànà tí Mose ti fi lélẹ̀, lojoojumọ, ati ní gbogbo ọjọ́ ìsinmi, ati ní ìbẹ̀rẹ̀ oṣù tuntun ati àwọn àjọ̀dún mẹta pataki tí wọ́n gbọdọ̀ ṣe lọdọọdun: àjọ àìwúkàrà, àjọ ìkórè ati àjọ ìpàgọ́.

14 Gẹ́gẹ́ bí ìlànà tí Dafidi fi lélẹ̀, Solomoni pín àwọn alufaa sí ìsọ̀rí-ìsọ̀rí láti máa ṣe iṣẹ́ ìsìn, ó sì pín àwọn ọmọ Lefi sí ìsọ̀rí-ìsọ̀rí láti máa kọ orin ìyìn ati láti máa ṣe ìrànlọ́wọ́ fún àwọn alufaa ninu iṣẹ́ wọn ojoojumọ. Ó yan àwọn aṣọ́nà sí oríṣìíríṣìí ẹnu ọ̀nà gẹ́gẹ́ bí Dafidi eniyan Ọlọrun ti pa á láṣẹ.

15 Wọn kò sì yapa kúrò ninu ìlànà tí Dafidi fi lélẹ̀ fún àwọn alufaa ati àwọn ọmọ Lefi nípa àwọn ohun tí wọ́n gbọdọ̀ máa ṣe, ati nípa ilé ìṣúra.

16 Bẹ́ẹ̀ ni Solomoni ṣe ṣe gbogbo iṣẹ́ tí ó ṣe láti ìgbà tí ó ti fi ìpìlẹ̀ ilé OLUWA lélẹ̀ títí di ìgbà tí ó parí iṣẹ́ náà patapata.

17 Solomoni lọ sí Esiongeberi ati Elati ní etí òkun ní ilẹ̀ Edomu.

18 Huramu fi àwọn ọkọ̀ ojú omi ati àwọn iranṣẹ rẹ̀ tí wọ́n mọ̀ nípa iṣẹ́ ọkọ̀ ojú omi ranṣẹ, wọ́n lọ sí ilẹ̀ Ofiri pẹlu àwọn iranṣẹ Solomoni, wọ́n sì kó ojilenirinwo ati mẹ́wàá (450) ìwọ̀n talẹnti wúrà wá fún Solomoni ọba.

orí

1 2 3 4 5 6 7 8 9 10 11 12 13 14 15 16 17 18 19 20 21 22 23 24 25 26 27 28 29 30 31 32 33 34 35 36