1 Solomoni ọba pinnu láti kọ́ tẹmpili níbi tí àwọn eniyan yóo ti máa sin OLUWA ati láti kọ́ ààfin fún ara rẹ̀.
2 Ó kó ọ̀kẹ́ mẹta ati ẹgbaarun (70,000) àwọn òṣìṣẹ́ jọ láti máa ru àwọn nǹkan tí yóo fi kọ́lé, ọ̀kẹ́ mẹrin (80,000) àwọn òṣìṣẹ́ tí yóo máa fọ́ òkúta, ati ẹẹdẹgbaaji ó lé ẹgbẹta (3,600) eniyan láti máa bojútó àwọn òṣìṣẹ́.
3 Solomoni ranṣẹ sí Huramu, ọba Tire pé, “Máa ṣe sí mi gẹ́gẹ́ bí o ti ṣe sí Dafidi, baba mi, tí o kó igi kedari ranṣẹ sí i láti kọ́ ààfin rẹ̀.
4 Mo fẹ́ kọ́ ilé ìsìn fún OLUWA Ọlọrun mi. Yóo jẹ́ ibi mímọ́ tí a ó ti máa sun turari olóòórùn dídùn níwájú rẹ̀. A ó máa mú ẹbọ àkàrà ojoojumọ lọ sibẹ, a ó sì máa rú ẹbọ sísun níbẹ̀ láàárọ̀ ati lálẹ́; ati ní ọjọọjọ́ ìsinmi, ati ní ìbẹ̀rẹ̀ oṣooṣù, ati ní gbogbo ọjọ́ àjọ̀dún OLUWA Ọlọrun wa, gẹ́gẹ́ bí ó ti pa á láṣẹ fún Israẹli títí lae.
5 Ilé tí mo fẹ́ kọ́ yóo tóbi pupọ, nítorí pé Ọlọrun wa tóbi ju gbogbo oriṣa lọ.
6 Kò sí ẹni tí ó lè kọ́ ilé fún un, nítorí pé ọ̀run, àní ọ̀run tí ó ga jùlọ, kò le è gbà á. Kí ni mo jẹ́ tí n óo fi kọ́ ilé fún un, bíkòṣe pé kí n kọ́ ibi tí a óo ti máa sun turari níwájú rẹ̀?
7 Nítorí náà, fi ẹnìkan ranṣẹ sí mi, tí ó mọ̀ nípa iṣẹ́ wúrà, fadaka, bàbà, ati irin, ẹni tí ó lè ṣiṣẹ́ ọnà sí ara aṣọ elése àlùkò, ati àlàárì, ati aṣọ aláwọ̀ aró, tí ó sì mọ̀ nípa iṣẹ́ gbẹ́nàgbẹ́nà. Yóo wà pẹlu àwọn òṣìṣẹ́ tí baba mi ti pèsè sílẹ̀, tí wọ́n wà pẹlu mi ní Juda ati Jerusalẹmu.
8 Kó igi kedari, sipirẹsi ati aligumu ranṣẹ sí mi láti Lẹbanoni. Mo mọ̀ pé àwọn iranṣẹ rẹ mọ̀ bí wọ́n ṣe ń gé igi ní Lẹbanoni, àwọn iranṣẹ mi náà yóo sì wà pẹlu wọn,
9 láti tọ́jú ọpọlọpọ igi, nítorí pé ilé tí mo fẹ́ kọ́ yóo tóbi, yóo sì jọjú.
10 N óo gbé ọ̀kẹ́ kan (20,000) ìwọ̀n kori ọkà tí a ti lọ̀, ati ọ̀kẹ́ kan (20,000) ìwọ̀n baali, ati ọ̀kẹ́ kan (20,000) ìwọ̀n bati ọtí, ati ọ̀kẹ́ kan (20,000) ìwọ̀n bati òróró fún àwọn iranṣẹ rẹ tí wọn yóo gé àwọn igi náà, wọn óo gbé wọn wá fún ọ.”
11 Huramu, ọba Tire, bá dá èsì lẹta Solomoni pada, ó ní, “OLUWA fẹ́ràn àwọn eniyan rẹ̀, ni ó ṣe fi ọ́ jọba lórí wọn.”
12 Ó tún fi kún un pé, “Ìyìn ni fún OLUWA Ọlọrun Israẹli tí ó dá ọ̀run ati ayé, tí ó fún Dafidi ní ọmọ tí ó gbọ́n, tí ó sì ní òye ati ìmọ̀ láti kọ́ tẹmpili fún OLUWA ati láti kọ́ ààfin fún ara rẹ̀.
13 Mo ti rán Huramu sí ọ; ó mọṣẹ́, ó sì ní làákàyè.
14 Ará Dani ni ìyá rẹ̀, ṣugbọn ará Tire ni baba rẹ̀. Ó mọ iṣẹ́ àgbẹ̀dẹ wúrà, ati ti fadaka, ti bàbà, ati ti irin; ó sì mọ òkúta, ati igi í gbẹ́. Ó mọ bí a tií ṣe iṣẹ́ ọnà sí ara aṣọ elése àlùkò, aṣọ aláwọ̀ aró, àlàárì, ati aṣọ ọ̀gbọ̀ onílà tẹ́ẹ́rẹ́tẹ́ẹ́rẹ́. Ó lè ṣe iṣẹ́ gbẹ́nàgbẹ́nà, ó sì lè ṣe oríṣìíríṣìí iṣẹ́ ọnà tí wọ́n bá ní kí ó ṣe pẹlu àwọn òṣìṣẹ́ tìrẹ, ati àwọn òṣìṣẹ́ oluwa mi, Dafidi, baba rẹ.
15 Nítorí náà, fi ọkà baali, òróró ati ọtí tí ìwọ oluwa mi ti ṣèlérí ranṣẹ sí èmi iranṣẹ rẹ.
16 A óo gé gbogbo igi tí o bá nílò ní Lẹbanoni, a óo sì tù wọ́n lójú omi wá sí Jọpa, láti ibẹ̀ ni ẹ lè wá kó wọn lọ sí Jerusalẹmu.”
17 Solomoni ka gbogbo àwọn àjèjì tí wọn ń gbé ilẹ̀ Israẹli gẹ́gẹ́ bí Dafidi baba rẹ̀ ti ṣe. Wọ́n jẹ́ ọ̀kẹ́ meje, ó lé ẹgbaaje ati ẹgbẹta (153,600).
18 Ó yan ọ̀kẹ́ mẹta ó lé ẹgbaarun (70,000) ninu wọn láti máa ru nǹkan ìkọ́lé, ó ní kí ọ̀kẹ́ mẹrin (80,000) eniyan máa la òkúta, kí ẹẹdẹgbaaji ó lé ẹgbẹta (3,600) jẹ́ alákòóso tí yóo máa kó wọn ṣiṣẹ́.