1 Àwọn ọmọ ilẹ̀ Juda bá fi Joahasi, ọmọ Josaya, jọba ní Jerusalẹmu lẹ́yìn baba rẹ̀.
2 Joahasi jẹ́ ẹni ọdún mẹtalelogun nígbà tí ó jọba, ó wà lórí oyè fún oṣù mẹta.
3 Ọba Ijipti ni ó lé e kúrò lórí oyè ní Jerusalẹmu, ó sì mú àwọn ọmọ Juda ní ipá láti máa san ọgọrun-un (100) ìwọ̀n talẹnti fadaka, ati ìwọ̀n talẹnti wúrà kan, gẹ́gẹ́ bí ìṣákọ́lẹ̀.
4 Neko, ọba Ijipti fi Eliakimu, arakunrin Joahasi jọba lórí Jerusalẹmu ati Juda, ó yí orúkọ rẹ̀ pada sí Jehoiakimu, ó sì mú Joahasi lọ sí Ijipti.
5 Ẹni ọdún mẹẹdọgbọn ni Jehoiakimu nígbà tí ó jọba. Ó wà lórí oyè ní Jerusalẹmu fún ọdún mọkanla. Ohun tí ó ṣe burú lójú OLUWA Ọlọrun rẹ̀.
6 Nebukadinesari, ọba Babiloni, gbógun tì í, ó sì fi ṣẹ́kẹ́ṣẹkẹ̀ dè é, ó fà á lọ sí Babiloni.
7 Nebukadinesari, ọba Babiloni, kó ninu àwọn ohun èlò ilé OLUWA lọ sí Babiloni, ó kó wọn sinu ààfin rẹ̀ ní Babiloni.
8 Àkọsílẹ̀ gbogbo nǹkan yòókù tí Jehoiakimu ṣe ati gbogbo ohun ìríra tí ó ṣe, ati àwọn àìdára rẹ̀ wà ninu Ìwé Ìtàn Àwọn Ọba Israẹli ati ti Juda. Jehoiakini, ọmọ rẹ̀ sì jọba lẹ́yìn rẹ̀.
9 Jehoiakini jẹ́ ọmọ ọdún mẹjọ nígbà tí ó jọba. Ó wà lórí oyè fún oṣù mẹta ati ọjọ́ mẹ́wàá ní Jerusalẹmu. Ohun tí ó ṣe burú lójú OLUWA.
10 Nígbà tí ọdún yípo, Nebukadinesari, ọba Babiloni ranṣẹ lọ mú un wá sí Babiloni pẹlu àwọn ohun èlò olówó iyebíye tí ó wà ninu ilé OLUWA. Ó sì fi Sedekaya, arakunrin rẹ̀ jọba ní Jerusalẹmu ati Juda.
11 Ẹni ọdún mọkanlelogun ni Sedekaya nígbà tí ó jọba. Ó wà lórí oyè ní Jerusalẹmu fún ọdún mọkanla.
12 Ohun tí ó ṣe burú lójú OLUWA Ọlọrun rẹ̀, kò rẹ ara rẹ̀ sílẹ̀ níwájú wolii Jeremaya ẹni tí Ọlọrun rán sí i láti bá a sọ̀rọ̀.
13 Sedekaya ṣọ̀tẹ̀ sí Nebukadinesari, bẹ́ẹ̀ sì ni Nebukadinesari ti fi ipá mú un búra ní orúkọ OLUWA pé kò ní ṣọ̀tẹ̀ sí òun. Ó ṣoríkunkun, ó sì kọ̀ láti yipada sí OLUWA Ọlọrun Israẹli.
14 Bákan náà, àwọn alufaa tí wọ́n jẹ́ aṣaaju ati àwọn eniyan yòókù pàápàá ṣe aiṣootọ sí OLUWA, wọ́n tẹ̀lé ìwà ìríra àwọn orílẹ̀-èdè tí ó yí wọn ká, wọ́n sì sọ ilé tí OLUWA ti yà sí mímọ́ ní Jerusalẹmu di aláìmọ́.
15 OLUWA Ọlọrun àwọn baba wọn kò dẹ́kun láti máa rán wolii sí wọn, nítorí pé àánú àwọn eniyan rẹ̀ ati ibùgbé rẹ̀ ń ṣe é.
16 Ṣugbọn, yẹ̀yẹ́ ni wọ́n ń fi àwọn iranṣẹ Ọlọrun ṣe. Wọn kò náání ọ̀rọ̀ rẹ̀, wọ́n sì ń kẹ́gàn àwọn wolii rẹ̀ títí tí OLUWA fi bínú sí wọn, débi pé kò sí àtúnṣe.
17 Ọlọrun mú kí ọba Kalidea gbógun tì wọ́n. Ọba náà fi idà pa àwọn ọdọmọkunrin Juda ninu tẹmpili, kò ṣàánú àwọn ọdọmọkunrin tabi wundia, tabi àwọn àgbà tabi arúgbó; gbogbo wọn ni Ọlọrun fi lé e lọ́wọ́.
18 Ọba Babiloni kó gbogbo ohun èlò ilé OLUWA, ati ńláńlá, ati kéékèèké, ati àwọn ìṣúra tí ó wà níbẹ̀, ati àwọn tí wọ́n wà ní ààfin ati ti ilé àwọn ìjòyè; ó kó gbogbo wọn patapata lọ sí Babiloni.
19 Wọ́n jó ilé OLUWA, wọ́n wó odi Jerusalẹmu, wọ́n jó ààfin ọba, wọ́n sì ba gbogbo nǹkan olówó iyebíye ibẹ̀ jẹ́.
20 Nebukadinesari kó gbogbo àwọn tí wọ́n kù tí wọn kò pa lẹ́rú, ati àwọn ọmọ wọn. Ó kó wọn lọ sí Babiloni, wọ́n sì ń sin òun ati àwọn ọmọ rẹ̀ títí di àkókò ìjọba Pasia;
21 kí ohun tí OLUWA ti sọ láti ẹnu wolii Jeremaya lè ṣẹ, pé, “Ilẹ̀ náà yóo di ahoro fún aadọrin ọdún kí ó lè ní gbogbo ìsinmi tí ó yẹ kí ó ti ní, ṣugbọn tí kò ní.”
22 Ní ọdún kinni ìjọba Kirusi, ọba Pasia, OLUWA mú ohun tí ó ti sọ láti ẹnu wolii Jeremaya ṣẹ. OLUWA fi sí Kirusi lọ́kàn, ó sì pàṣẹ jákèjádò ìjọba rẹ̀. Ó kọ àṣẹ náà sílẹ̀ báyìí pé:
23 “Èmi Kirusi, ọba Pasia, ni mo pàṣẹ yìí pé, ‘OLUWA Ọlọrun ọ̀run ni ó fún mi ní ìjọba lórí gbogbo ayé, òun ni ó sì ti pàṣẹ fún mi pé kí n kọ́ ilé kan fún òun ní Jerusalẹmu ní ilẹ̀ Juda. Nítorí náà, gbogbo àwọn tí wọ́n bá jẹ́ tirẹ̀ lára yín, kí wọ́n lọ sibẹ, kí OLUWA Ọlọrun wọn wà pẹlu wọn.’ ”