Kronika Keji 25 BM

Amasaya, Ọba Juda

1 Ẹni ọdún mẹẹdọgbọn ni Amasaya nígbà tí ó jọba; ó sì wà lórí oyè fún ọdún mọkandinlọgbọn ní Jerusalẹmu. Ìyá rẹ̀ ni Jehoadini ará Jerusalẹmu.

2 Ó ṣe ohun tí ó dára lójú OLUWA, ṣugbọn kò fi tọkàntọkàn sìn ín.

3 Lẹ́yìn ìgbà tí ìjọba rẹ̀ ti fẹsẹ̀ múlẹ̀, ó pa gbogbo àwọn tí wọ́n pa baba rẹ̀.

4 Ṣugbọn kò pa àwọn ọmọ wọn, gẹ́gẹ́ bí ìwé òfin Mose ti wí, níbi tí OLUWA ti pàṣẹ, pé, “A kò gbọdọ̀ pa baba nítorí ẹ̀ṣẹ̀ ọmọ, tabi kí á pa ọmọ nítorí ẹ̀ṣẹ̀ baba; olukuluku ni yóo kú nítorí ẹ̀ṣẹ̀ ara rẹ̀.”

Wọ́n Gbógun ti Edomu

5 Amasaya pe àwọn eniyan Juda ati Bẹnjamini jọ, ó pín wọn sábẹ́ àwọn ọ̀gágun ní ẹgbẹẹgbẹrun ati ọgọọgọrun-un gẹ́gẹ́ bí ilé baba wọn. Àwọn tí wọ́n tó ẹni ogún ọdún ati jù bẹ́ẹ̀ lọ ni gbogbo àwọn tí ó kó jọ. Gbogbo wọn jẹ́ ọ̀kẹ́ mẹẹdogun (300,000) akọni ọkunrin tí wọ́n tó lọ sójú ogun, tí wọ́n sì lè lo ọ̀kọ̀ ati apata.

6 Ó tún fi ọgọrun-un ìwọ̀n talẹnti fadaka lọ bẹ ọ̀kẹ́ marun-un (100,000) akọni lọ́wẹ̀ ninu àwọn ọmọ ogun Israẹli.

7 Ṣugbọn wolii Ọlọrun kan lọ bá Amasaya, ó sọ fún un pé, “Kabiyesi, má jẹ́ kí àwọn ọmọ ogun Israẹli bá ọ lọ, nítorí OLUWA kò ní wà pẹlu Israẹli ati àwọn ará Efuraimu wọnyi.

8 Ṣugbọn bí o bá wá rò pé àwọn wọnyi ni yóo jẹ́ kí ogun rẹ lágbára, OLUWA yóo bì ọ́ ṣubú níwájú àwọn ọ̀tá rẹ. Nítorí Ọlọrun lágbára láti ranni lọ́wọ́ ati láti bini ṣubú.”

9 Amasaya bèèrè lọ́wọ́ wolii náà pé, “Kí ni kí á ṣe nípa ọgọrun-un talẹnti tí mo ti fún àwọn ọmọ ogun Israẹli?”Ó dáhùn pé, “OLUWA lè fún ọ ní ohun tí ó jù bẹ́ẹ̀ lọ.”

10 Nítorí náà Amasaya dá àwọn ọmọ ogun Efuraimu tí ó gbà pada sílé wọn. Nítorí náà, inú bí wọn gan-an sí Juda, wọ́n sì pada sílé pẹlu ìrúnú.

11 Ṣugbọn Amasaya fi ìgboyà kó ogun rẹ̀ lọ sí Àfonífojì Iyọ̀, ó sì pa ẹgbaarun (10,000) ninu àwọn ọmọ ogun Seiri.

12 Wọ́n mú ẹgbaarun (10,000) mìíràn láàyè, wọ́n kó wọn lọ sí góńgó orí òkè kan, wọ́n jù wọ́n sí ìsàlẹ̀, gbogbo wọn sì ṣègbé.

13 Àwọn ọmọ ogun Israẹli tí Amasaya dá pada, tí kò jẹ́ kí wọ́n tẹ̀lé òun lọ sógun bá lọ, wọ́n kọlu àwọn ìlú Juda láti Samaria títí dé Beti Horoni. Wọ́n pa ẹgbẹẹdogun (3,000) eniyan, wọ́n sì kó ọpọlọpọ ìkógun.

14 Amasaya kó oriṣa àwọn ará Edomu tí ó ṣẹgun wá sílé. Ó kó wọn kalẹ̀, ó ń bọ wọ́n, ó sì ń rúbọ sí wọn.

15 Inú bí OLUWA sí Amasaya gan-an, ó sì rán wolii kan sí i kí ó sọ fún un pé, “Kí ló dé tí o fi ń bọ àwọn oriṣa tí kò lè gba àwọn eniyan rẹ̀ lọ́wọ́ rẹ?”

16 Bí wolii yìí ti ń sọ̀rọ̀ lọ́wọ́ ni ọba dá a lóhùn pé, “Panumọ́, ṣé wọ́n fi ọ́ ṣe olùdámọ̀ràn ọba ni? Àbí o fẹ́ kú ni.”Wolii náà bá dákẹ́, ṣugbọn, kí ó tó dákẹ́ ó ní, “Mo mọ̀ pé Ọlọrun ti pinnu láti pa ọ́ run fún ohun tí o ṣe yìí, ati pé, o kò tún fetí sí ìmọ̀ràn mi.”

Amasaya Gbógun ti Israẹli

17 Lẹ́yìn tí Amasaya, ọba Juda, ṣe àpérò pẹlu àwọn olùdámọ̀ràn rẹ̀, ó ranṣẹ sí Jehoaṣi ọmọ Jehoahasi, ọmọ Jehu, ọba Israẹli pé, “Wá, jẹ́ kí á kojú ara wa.”

18 Jehoaṣi ọba Israẹli ranṣẹ sí ọba Juda pé, “Ní àkókò kan, ẹ̀gún ẹ̀wọ̀n kan ní Lẹbanoni ranṣẹ sí igi kedari ní Lẹbanoni pé, ‘Mo fẹ́ fẹ́ ọmọbinrin rẹ fún ọmọkunrin mi.’ Ẹranko ìgbẹ́ kan ń kọjá lọ, ó sì tẹ ẹ̀gún náà mọ́lẹ̀.

19 O bẹ̀rẹ̀ sí fọ́nnu pẹlu ìgbéraga pé o ti ṣẹgun àwọn ará Edomu, ṣugbọn, mo gbà ọ́ ní ìmọ̀ràn pé kí o dúró jẹ́ẹ́ sí ilé rẹ. Kí ló dé tí ò ń fi ọwọ́ ara rẹ fa ìjàngbọ̀n tí ó lè fa ìṣubú ìwọ ati àwọn eniyan rẹ?”

20 Ṣugbọn Amasaya kọ̀, kò gbọ́, nítorí pé Ọlọrun ni ó mú kí ọkàn rẹ̀ le, kí Ọlọrun lè fi Juda lé àwọn ọ̀tá wọn lọ́wọ́ nítorí pé wọ́n ń bọ àwọn oriṣa Edomu.

21 Nítorí náà, Jehoaṣi, ọba Israẹli, gòkè lọ, òun ati Amasaya ọba Juda sì kojú ara wọn lójú ogun ní Beti Ṣemeṣi ní ilẹ̀ Juda.

22 Àwọn ará Israẹli ṣẹgun àwọn ará Juda, olukuluku sì fọ́nká lọ sí ilé rẹ̀.

23 Jehoaṣi, ọba Israẹli mú Amasaya, ọba Juda, ọmọ Joaṣi, ọmọ Ahasaya, ní ojú ogun, ní Beti Ṣemeṣi; ó sì mú un wá sí Jerusalẹmu. Ó wó odi Jerusalẹmu palẹ̀ láti Ẹnubodè Efuraimu títí dé Ẹnubodè Kọ̀rọ̀. Gígùn ibi tí à ń wí yìí jẹ́ irinwo igbọnwọ (200 mita.)

24 Ó kó gbogbo wúrà, fadaka ati àwọn ohun èlò tí ó wà lábẹ́ ìtọ́jú Obedi Edomu ní ilé Ọlọ́run. Lẹ́yìn náà, ó lọ sí ààfin ọba, ó kó gbogbo ìṣúra tí ó wà níbẹ̀ ati àwọn eniyan, ó sì pada sí Samaria.

25 Amasaya, ọmọ Joaṣi, ọba Juda gbé ọdún mẹẹdogun lẹ́yìn ikú Jehoaṣi, ọmọ Jehoahasi, ọba Israẹli.

26 Àkọsílẹ̀ àwọn nǹkan yòókù tí Amasaya ṣe, láti ìbẹ̀rẹ̀ dé òpin, wà ninu ìwé àwọn ọba Juda ati Israẹli.

27 Láti ìgbà tí Amasaya ti pada lẹ́yìn OLUWA ni àwọn eniyan ti dìtẹ̀ mọ́ ọn ní Jerusalẹmu, nítorí náà, ó sá lọ sí Lakiṣi. Ṣugbọn wọ́n lépa rẹ̀ lọ sí Lakiṣi, wọ́n sì pa á níbẹ̀.

28 Wọ́n fi ẹṣin gbé òkú rẹ̀ wá sí Jerusalẹmu, wọ́n sì sin ín sí ìlú Dafidi ní ibojì àwọn baba rẹ̀.

orí

1 2 3 4 5 6 7 8 9 10 11 12 13 14 15 16 17 18 19 20 21 22 23 24 25 26 27 28 29 30 31 32 33 34 35 36