Kronika Keji 18 BM

Wolii Mikaya Kìlọ̀ fún Ahabu

1 Nígbà tí Jehoṣafati ọba Juda di ọlọ́rọ̀ ati olókìkí, ó fẹ́ ọmọ Ahabu kí ó lè ní àjọṣepọ̀ pẹlu Ahabu.

2 Lẹ́yìn ọdún díẹ̀, Jehoṣafati lọ sí ìlú Samaria láti bẹ Ahabu wò. Láti dá Jehoṣafati lọ́lá pẹlu àwọn tí wọ́n bá a wá, Ahabu pa ọpọlọpọ aguntan ati mààlúù fún àsè. Ó rọ Jehoṣafati láti bá òun lọ gbógun ti ìlú Ramoti Gileadi.

3 Ahabu, ọba Israẹli bèèrè lọ́wọ́ rẹ̀ pé, “Ṣé o óo bá mi lọ gbógun ti Ramoti Gileadi?”Jehoṣafati dáhùn pé, “Tìrẹ ni èmi ati àwọn eniyan mi, a óo bá ọ lọ jagun náà.”

4 Ṣugbọn Jehoṣafati sọ fún ọba Israẹli pé, “Jẹ́ kí á kọ́kọ́ bèèrè lọ́wọ́ OLUWA ná.”

5 Nítorí náà, Ahabu pe gbogbo àwọn Wolii jọ, gbogbo wọn jẹ́ irinwo (400). Ó bi wọ́n pé, “Ṣé kí á lọ gbógun ti Ramoti Gileadi tabi kí á má lọ?”Wọ́n dáhùn pé, “Lọ gbógun tì í, Ọlọrun yóo fún ọ ní ìṣẹ́gun.”

6 Ṣugbọn Jehoṣafati bèèrè lọ́wọ́ Ahabu pé, “Ṣé kò sí wolii OLUWA mìíràn mọ́ tí a lè bèèrè lọ́wọ́ rẹ̀?”

7 Ahabu dáhùn pé, “Ó ku ọ̀kan tí à ń pè ní Mikaya, ọmọ Imila tí a lè bèèrè lọ́wọ́ rẹ̀. Ṣugbọn mo kórìíra rẹ̀, nítorí pé àsọtẹ́lẹ̀ rere kan kò ti ẹnu rẹ̀ jáde sí mi rí, àfi kìkì burúkú.”Jehoṣafati dáhùn, ó ní, “Má sọ bẹ́ẹ̀.”

8 Nítorí náà, Ahabu ọba pe ọ̀kan ninu àwọn iranṣẹ rẹ̀ kí ó lọ pe Mikaya wá kíákíá.

9 Àwọn ọba mejeeji gúnwà lórí ìtẹ́ wọn, ní ibi ìpakà, ní àbáwọ bodè Samaria, gbogbo àwọn wolii sì bẹ̀rẹ̀ sí sọ àsọtẹ́lẹ̀ níwájú wọn.

10 Ọ̀kan ninu àwọn wolii tí à ń pè ní Sedekaya, ọmọ Kenaana ṣe àwọn ìwo irin kan, ó sì sọ fún Ahabu pé, “OLUWA ní, pẹlu àwọn ìwo wọnyi ni o óo fi bi àwọn ará Siria sẹ́yìn, títí tí o óo fi run wọ́n patapata.”

11 Àwọn wolii yòókù ń sọ bákan náà, wọ́n ń wí pé, “Lọ gbógun ti Ramoti Gileadi, o óo ṣẹgun. OLUWA yóo fi wọ́n lé ọba lọ́wọ́.”

12 Iranṣẹ tí ó lọ pe Mikaya sọ fún un pé, “Àsọtẹ́lẹ̀ kan náà ni gbogbo àwọn wolii ń sọ, pé ọba yóo ṣẹgun, ìwọ náà sọ bẹ́ẹ̀.”

13 Ṣugbọn Mikaya dáhùn pé, “Mo fi orúkọ OLUWA búra pé ohun tí Ọlọrun bá sọ fún mi pé kí n sọ ni n óo sọ.”

14 Nígbà tí ó dé iwájú Ahabu, Ahabu bèèrè lọ́wọ́ rẹ̀ pé, “Mikaya, ṣé kí á lọ gbógun ti Ramoti Gileadi tabi kí á má ṣe lọ?”Mikaya dáhùn pé, “Ẹ lọ gbógun tì í, OLUWA yóo fi wọ́n lé yín lọ́wọ́, ẹ óo sì ṣẹgun.”

15 Ṣugbọn Ahabu bi í pé, “Ìgbà mélòó ni mo níláti mú ọ búra pé kí o máa sọ òtítọ́ fún mi ní orúkọ OLUWA?”

16 Mikaya bá sọ pé, “Mo rí i tí gbogbo ọmọ ogun Israẹli fọ́n káàkiri lórí òkè, bí aguntan tí kò ní olùṣọ́. OLUWA bá sọ pé, ‘Àwọn eniyan wọnyi kò ní olórí. Jẹ́ kí olukuluku máa lọ sí ilé rẹ̀ ní alaafia.’ ”

17 Ọba Israẹli wí fún Jehoṣafati pé, “Ṣé o ranti pé mo ti sọ pé kò sọ àsọtẹ́lẹ̀ rere fún mi rí? Àsọtẹ́lẹ̀ burúkú nìkan ni òun máa ń sọ.”

18 Mikaya bá dáhùn pé, “Gbọ́ ohun tí OLUWA sọ! Mo rí OLUWA, ó jókòó lórí ìtẹ́ rẹ̀, àwọn ogun ọ̀run sì wà ní apá ọ̀tún ati apá òsì rẹ̀.

19 OLUWA bèèrè pé, ‘Ta ni yóo lọ tan Ahabu, ọba Israẹli, kí ó lè lọ sí Ramoti Gileadi, kí ó sì kú níbẹ̀.’ Bí àwọn kan tí ń sọ nǹkankan, ni àwọn mìíràn ń sọ nǹkan mìíràn.

20 Nígbà náà ni ẹ̀mí kan jáde, ó sì dúró níwájú OLUWA, ó ní, ‘N óo lọ tan Ahabu jẹ.’ OLUWA bá bèèrè pé, ‘Ọgbọ́n wo ni o fẹ́ dá?’

21 Ẹ̀mí náà dáhùn pé, ‘N óo lọ sọ gbogbo àwọn wolii Ahabu di wolii èké.’ OLUWA bá dá a lóhùn pé, ‘Ìwọ ni kí o lọ tàn án jẹ, o óo sì ṣe àṣeyọrí, lọ ṣe bí o ti wí.’ ”

22 Mikaya ní, “OLUWA ni ó mú kí àwọn wolii rẹ wọnyi máa sọ àsọtẹ́lẹ̀ èké, ṣugbọn àjálù burúkú ni OLUWA ti pinnu pé yóo dé bá ọ.”

23 Nígbà náà ni Sedekaya, ọmọ Kenaana súnmọ́ Mikaya, ó gbá a létí, ó wí pé, “Nígbà wo ni ẹ̀mí OLUWA fi mí sílẹ̀ tí ó wá ń bá ọ sọ̀rọ̀?”

24 Mikaya dáhùn pé, “Ojú rẹ yóo já a ní ọjọ́ náà, nígbà tí o bá lọ sá pamọ́ sí kọ̀rọ̀ yàrá.”

25 Nígbà náà ni Ahabu ọba pàṣẹ pé kí wọ́n mú Mikaya lọ sọ́dọ̀ Amoni, gomina ìlú ati sọ́dọ̀ Joaṣi, ọmọ ọba, kí wọ́n sì sọ fún wọn pé:

26 Ẹ ju ọkunrin yìí sẹ́wọ̀n, kí wọ́n sì máa fún un ní omi ati burẹdi nìkan títí òun óo fi pada dé ní alaafia.

27 Mikaya dáhùn pé, “Tí o bá pada dé ní alaafia, a jẹ́ pé kì í ṣe OLUWA ni ó gba ẹnu mi sọ̀rọ̀.” Ó sì tún sọ siwaju sí i pé, kí olukuluku fetí sí ohun tí òun wí dáradára.

Ikú Ahabu

28 Ahabu ọba Israẹli ati Jehoṣafati ọba Juda lọ gbógun ti Ramoti Gileadi.

29 Ahabu sọ fún Jehoṣafati pé, “Bí a ti ń lọ sógun yìí, n óo yí ara pada. Ṣugbọn ìwọ ní tìrẹ, wọ aṣọ ìgúnwà rẹ.” Ọba Israẹli bá yíra pada, ó lọ sí ojú ogun.

30 Ọba Siria ti pàṣẹ fún àwọn ọ̀gágun tí wọn ń ṣàkóso àwọn kẹ̀kẹ́ ogun rẹ̀ pé kí wọ́n má ṣe bá ẹnikẹ́ni jà bíkòṣe ọba Israẹli nìkan.

31 Nítorí náà, nígbà tí wọ́n rí Jehoṣafati, wọ́n rò pé ọba Israẹli ni, wọ́n bá yíjú sí i láti bá a jà. Jehoṣafati bá bẹ̀rẹ̀ sí kígbe, OLUWA sì gbà á sílẹ̀ lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá.

32 Nígbà tí àwọn ọ̀gágun náà rí i pé kì í ṣe Ahabu, ọba Israẹli, wọ́n pada lẹ́yìn rẹ̀.

33 Ṣugbọn ọmọ ogun Siria kan déédé ta ọfà rẹ̀, ọfà náà sì bá Ahabu ọba níbi tí ìgbàyà ati ihamọra rẹ̀ ti pàdé. Ó bá kígbe sí ẹni tí ó ru ihamọra rẹ̀ pé, “Mo ti fara gbọgbẹ́, yipada kí o gbé mi kúrò lójú ogun.”

34 Ogun gbóná ní ọjọ́ náà, Ahabu ọba bá rá pálá dìde dúró, wọ́n fi ọwọ́ mú un ninu kẹ̀kẹ́ ogun rẹ̀, ó kọjú sí ogun Siria. Ṣugbọn nígbà tí oòrùn ń wọ̀ lọ, ó kú.

orí

1 2 3 4 5 6 7 8 9 10 11 12 13 14 15 16 17 18 19 20 21 22 23 24 25 26 27 28 29 30 31 32 33 34 35 36